IGBEKELE OLORUN LOJU
Ore ti o dara ju fun Dafidi (Ahiotofeli) daa, o si fe ki o ku, ni gbogbo ona, ki o ba le ni igbega lati owo Absalomu. Ahitofeli mo Dafidi daradara, o ti nse afokan tan fun un fun opolopo odun. O mo agbara ati ailagbara Dafidi, o si setan lati dale re, kio ba le ri ipo Pataki pelu Absalomu ti o ti gba ijoba baba re. Dafidi mo ewu ti o yii ka. Nitorina, o kepe olorun fun iranlọwo, Dafidi be olorun ki o so imoran Ahitofeli di asan, eyi gan ni Olorun se. Imoran Ahitofeli ko wulo fun Absalomu, itiju de baa. Olote yi ni idamu titi o fi pa ara re. Iyanu nla ni bi Olorun se ran Dafidi alailagbara lati segun ni akoko to nira yi.
EKO
Awon eniyan buburu ko le fege titi lae, olorun yio fiya je won. Niwon igba ti olorun ni agbara lati mu enikeni, yio mu awon eniyan buburu, yi o si fiya je won bo tito. Awon omo olorun ti o ba njiya dida ore ati ijakule, ki o mu okan le. Olorun yio ja fun won, yi o si gbe won nija fun itelorun re. A ro awon omo olorun ki won fi igbekele won sinu Olorun. A ko ni lati gbekele arakunrin tabi arabinrin, a ni lati gbekele olorun. Eniyan ni alebu sugbon Olorun ko ni. Bi eniyan ba ja wa kule, Olorun ko ni ja wa kule.
ADURA
Olorun olufe, jowo ko mi bi mo sele gbeke le o ni gbogbo ona aye mi. Mase je ki nfi igbekele mi si eniyan, eni to ni alebu. Je ki nfi gbogbo igbekele mi sinu re ni gbogbo igba. Fun mi ni igboya wipe iwo yi o ja fun mi, bi emi ko tile wa ni tosi. Abo re yi o daju lori mi, o ko si ni je ki ota pin ninu ogo re ninu aye mi. Mo gbadura ni oruko omo re Jesu Kristi. Amin.
